Articles

Nípa Ìkán-jù-kàn àti Ìpọ̀sí Èdè Nínú Lítiíréṣọ̀ Ilẹ̀ Afíríkà

By: Kọ́lá Túbọ̀sún,

Ó ti pé tí a ti máa ń gbọ́ àríyànjiyàn nípa kíni irú èdè tí ó yẹ ká lò láti máa kọ lítíréṣọ̀ nílẹ̀ adúláwọ̀. Ṣùgbọ́n ṣè kò tíì pẹ́ ju bẹ́ẹ̀ lọ tí àwọn ọmọ ilẹ̀ adúláwọ̀ ti ń ṣe oríṣiríṣi iṣẹ́ ọnà nínú èdè wọn? Ṣèbí a ti ń kọrin, kéwì, a sì ti ń ṣe oríṣiríṣi oun ọnà àti àrà fúnra wa kí àwọn òyìbó amúnisìn tó dé. K’ágbàdo tó dáyé, kiníkan l’adìyẹ ń jẹ. Torípé a kìí kọ wọ́n sílẹ̀ kò túmọ̀ sí pé a kò ní nǹkan àṣà tiwa.

Nítorínáà, nígbà tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa irú èdè tó yẹ ká fi kọ lítíréṣọ̀, ṣé kò yẹ ká bèèrè ìdí tí àwọn oun tí a ti ṣe sẹ́yìn nínú àwọn èdè wa kò fi jẹ́ pàtàkì nínú ìjíròrò yìí ni? Ṣé oun tí a kọ sílẹ̀ nìkan ló ṣe pàtàkì ju oun tí a ṣẹ̀dá ẹ̀ lọ́nà mìíràn ni?

Nínú ìpàdé wa yìí, mo fẹ́ jíròrò pẹ̀lú yín nípa àwọn ọ̀rọ̀ yìí. A ó ka àwọn ohun tí àwọn aṣíwájú ti sọ nípa ìlo èdè ní lítíréṣọ̀, ṣùgbọ́n a ó tún sọ̀rọ̀ nípa bóyá ààyè díẹ̀ tún wà fún wa láti gbélárugẹ àwọn èdè àti àṣà tiwa gangan lọ́nà tí àwọn ará àgbáyé á fi lè bá wa gbàá bí wọ́n ṣe gba tiwọn.

Read this blog in English here.

Sign up for the Radical Approaches Reading Group 3- Language Hegemony in African Literature with Kọ́lá Túbọ̀sún here.