Poems

Máfipáwówó

Ẹ métí bora kẹ́ gbóhun tí mo fẹ́ wí orin ewì ń gbé mi nínú
Ibi mo sọ̀rọ̀ dé ni ngó fàbọ̀ sí
Orin ọgbọ́n ṣẹ́kù nínú mi
Orin olówó lorin tó yó sí mi lẹnu
Kò sí gbàrọgùdù mọ́, orin olówó ló kù nílẹ̀
Mo ní b’ọ́lọ́lá ayé ti lọ́lá tó
Ọlọ́lá ò le sùn kó dijú tán
Owó ni wọ́n tún fi ojojúmọ́ lé pa kiri
Àjáàjo ò sì jẹ́ kí wọ́n rí ìhà méjééjì sùn
Wọn ò ráyè sùn lálẹ́
Wọn ò ráyè orun lójú mọmọ
Bẹ́ẹ̀ni àsùnfalala àsùnjátọ́ lọmọ tálákà ń sùn
Àá ti gbọ́ pé èèyàn lówó tán irú wọn ò tún kófà orun
Ka rójú tán ka tún mọ́ọ wákú kiri 
Ká ti rírọ̀rùn tán, ká mọ́ọ wá wàhálà
Nítòótọ́ ni mo gbọ́ pé olúṣekún ìná kìí tánwó
Owó táa ṣiṣẹ́ fún ní lọ́ra lọ́wọ́ ẹni
Ẹ̀mí owó ò lè gùn fẹ́ni tó bá ń sùn sílẹ̀
Ṣugbọn béyàn bá lówó ó yẹ kó tún lè nísinmi
Èwo ni ká wówówówó ká wá dẹrú owó
Kọ́mọ ẹ̀dá ó ma rọ́jú kẹ̀wù ìdàmú bọra rẹ̀ lọ́rùn
Ká sáré lọ ní kùtùkùtù ìdájí ká wọlé lọ́gànjọ́ lóru
Kójú ó tó mọ́ ká ti tún lọ
Ká máa ṣe kìtàkìtà ní gbogbo àkókò
Ẹ bá mi wí fólówó
Kí wọn ó yé tọwọ́ bọ ikú lójú
Kí ọmọ èyàn ó sinmi díẹ̀ kí ó ṣiṣẹ́ díẹ̀ ló tọ̀nà
Ẹ bá mi sọ fún ọlọ́rọ̀ kó fúnra rẹ̀ láàyè ìsinmi
Kó le hu irun funfun lórí kó tó lọ sálákeji
Èyàn tí ò bá sinmi ní kú láyì tásìkò
Ìhòhò pátá la kúkú rìn wáyé, ọwọ́ lọmọ ẹ̀dá ń sán r’ọ̀run
Kóní kálùlù ó yé pára rẹ̀ láyà

Share this poem

view comments

Comments (0)

No comments yet - be the first:

Leave a comment