Poems

Adúmáadán

Bí a bá mú egbin kúrò láwùjọ ẹranko
Ẹranko tó dára ti tán
Bí a bá mú òdú kúrò láwùjọ ẹ̀fọ́
Ẹ̀fọ́ tó dára tó jọjú ti dínkù
Ẹni tó fọ́jú mẹwà egbin bí ó bá fọwọ́ pa á lára
Àńbọ̀sìbọ́sí ẹni tó lẹ́yinjú méjèèjì
Adúmáadán obìnrin ló múmi rántí
Ẹranko tó wuyì láwùjọ ẹranko
Dúdúparíọlá olólùfẹ́ ló múmi dárúkọ òdú láwùjọ ẹ̀fọ́
Ó dúdú ó rì rébété
Eyín funfun nígínnígín
Ètè ìwọ̀ntúnwọ̀nsì ló sì bo gbogbo wọn
Bójú bá ti pàdé lojú ń rinjú
Bí n bá ti wò ẹ́ ni mò ń yin Yáárábì nísàlú-ọ̀run
Ìfẹ́ mú mi títí
Ojú ń ro mí
Mo ń dá rẹ́rìn-ín nígbà gbogbo
Báráyé bá bi mi pé kí ló dé
Gorodóòmù ìfẹ́ adúmáadán ló démi mọ́lẹ̀ pirigidi.