Poems

Nínú Ọgbà Ayọ̀

Ọgbà àjàrà ayọ̀ la wà yìí
Dè mí kí n má lè rọ́nà yí
Tilẹ̀kùn ọgbà àjàrà
Kí nwọn ó máa gbẹ́kùlé wàrà.
Kàn’lù ìfẹ́ sí mi
Kí n jó dùndún ìfẹ́ mọ́jú
Ràdò ìfẹ́ bò mí
Má jẹ̀ẹ́ n ké’gbe òtútù.
 
Bẹ́ẹ̀ bá wá’únjẹ wọ́gbà yìí wá
Afẹ́fẹ́ ìfẹ́ leè yó’kùn-un wa
Báà wẹ̀ lógún ọdún
Omi ìfẹ́ le wẹ̀ wá nù
Báà kọ́ yààrá ńlá
Ìfẹ́ ń ṣe yààrá bò wá
Kóṣùpá ìfẹ́ ó máa ràn lọ́dọ̀ọ wa
Ká pèjì pọ̀
Ká fi fẹ́ná ìfẹ́ jò.